O dami loju pe awọn ara Kwara ko tun le pada s'idi eebi wọn mọ lailai - AbdulRazaq sọrọ soke - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 23, 2022

O dami loju pe awọn ara Kwara ko tun le pada s'idi eebi wọn mọ lailai - AbdulRazaq sọrọ soke


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe ohun kan ṣoṣo to da oun loju gbangba ni pe awọn ara ati olugbe ipinlẹ naa ko tun le pada sibi eebi wọn mọ lailai.
 
O ni ọrọ ẹgbẹ oṣelu alatako, iyẹn Peoples Democratic Party, PDP ti di ohun igbagbe patapata, nitori pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti mu pupọ awọn ileri wọn ṣẹ f'awọn araalu.

AbdulRazaq sọrọ yii nibi iṣide ipolongo idibo ọdun 2023 fun aṣoju-ṣofin agba, Raheem Tunji Olawuyi Ajulo-opin to waye niluu Omu Aran.
 
Nibẹ ni gomina ti sọ pe ẹgbẹ awọn ti rii daju wọn ṣe ohun gbogbo ti araalu n fẹ, ni oniruuru ẹka to so ipinlẹ naa papọ lai ṣe ojusaaju, ati pe ileri ti wọn ṣe lo wa si imuṣẹ lati gbe Kwara de ibi to yẹ ko wa.

O ṣapejuwe ipadabọ ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bi ẹni to yagbẹ sile to ya gbe, ṣugbọn ti ẹlomiran ti tun gbogbo rẹ ṣe, to si tun wa fẹẹ pada sinu ile naa. O ni ko saaye mọ fun wọn.

"Wọn tun fẹẹ da wa pada sẹyin ni. Rara, ko le ṣeeṣe. A ti tẹsiwaju nipinlẹ Kwara. Se ni eto ẹkọ ni ka sọ ni, emi ẹrọ igbalode, igbayegbadun awọn oṣiṣẹ, idagbasoke igberika ati agbegbe ẹ abi ti eto ilera ni ka sọ ni? Ki ni awọn ipa wọn, ti yoo le mu ki wọn tun pada wa?" AbdulRazaq.

AbdulRazaq wa sọ fun gbogbo ọmọ ipinlẹ naa lati dibo lọpọ yanturu fun ẹgbẹ oṣelu APC lakoko eto idibo to n bọ lọna yii
 




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI