Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bura fun n'ipinlẹ Ekiti, Biọdun Oyebanji ti sọ pe oun ti fa ipinlẹ naa le Oluwa lọwọ lati maa ṣakoso rẹ fun itọni ati akoso.
Oyebanji sọrọ yii lakoko adura ranpẹ to waye ninu ile-igbe gomina, Government House Chapel to wa niluu Ado-Ekiti l'ọjọ Aje, Mọnde to kọja.
Lara awọn to wa nibẹ ni iyawo rẹ, Ọmọwe Ọlayẹmi Oyebanji, olori awọn oṣiṣẹ, Amofin Bamidele Agbẹdẹ.
Nibẹ ni Gomina ti sọ pe oun nilo lati fa ipinlẹ naa le Ọlọrun lọwọ lọjọ akọkọ ti iṣẹ bẹrẹ, koun si le jẹ ki Oluwa gba akoso gbogbo iṣẹ toun yoo dawọ le.
No comments:
Post a Comment