Mi o tii juwọ silẹ lati dije du ipo aarẹ Naijiria o - Tinubu pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 3, 2022

Mi o tii juwọ silẹ lati dije du ipo aarẹ Naijiria o - Tinubu pariwo sita


Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ati oludije du ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ naa, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, ti pariwo sita wi pe ko si otitọ kankan nipa iroyin to n kaakiri ori ayelujara wi pe oun ti juwọ silẹ lati jade du ipo aarẹ orileede yii.

Ori ikanni ayelujara ni Tinubu ti sọrọ naa jade lalẹ ọjọ Aiku, Sannde to kọja, nigba to n gbe fọnran kan jade sita, eyi to fi tako iroyin naa, to si ni digbi lara ọta oun le koko.

Tinubu nigba to n sọrọ, o ni “Ọpọ awọn eeyan lo n sọ pe mo ti ku; awọn miran sọ pe mo ti juwọ silẹ lati ṣe ipolongo idibo aarẹ to n bọ lọna. Rara o... Ko ri bẹẹ.

“Otitọ ibẹ ree: Ara mi le koko, Mo duro digbi, mo si ṣetan lati sin awọn ọmọ orileede Naijiria lati ọjọ akọkọ mi.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI