L'Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni awọn ara ipinlẹ Kwara sọrọ sita wi pe kii ṣe t'ẹnu, bẹẹ si ni kii ṣe asọdun wi pe pupọ awọn aṣeyọri iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo ṣee f'oju ri, ti awọn si n ni imọlara rẹ kaakiri ilu.
Nibi ipade ita gbangba, iyẹn Town Hall Meeting ti gomina ṣe pẹlu awọn araalu, eyi to waye niluu Ọffa ni wọn ti sọrọ naa jade, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe o ti di dandan k'awọn dibo yan an s'ipo lẹẹkeji.
Ipade ita gbangba naa ni Gomina AbdulRazaq ṣe lati fi ba awọn araalu sọrọ, paapaa bi eto ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress, APC ṣe bẹrẹ ni ipẹrẹu.
Nibẹ l'awọn alẹnulọrọ, alakoso eto iṣejọba, alakoso ileeṣẹ ijọba at'awọn ti ọrọ kan ti ba awọn araalu sọrọ nipa idagbasoke to ti waye lasiko ti Gomina AbdulRazaq gba ijọba.
Bakan naa n'ijọba tun ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa awọn akanṣe iṣẹ tuntun, ilana iṣejọba tuntun, at'awọn miran ti wọn fẹẹ dawọ le, bẹẹ ni wọn tun gba oriṣiriṣi ibeere lati ọdọ awọn araalu.
Kaakiri agbegbe ati igberiko ni iṣakoso yii ti ṣiṣẹ takuntakun lẹka eto ẹkọ, ohun amayedẹrun bii opopona to ja geere, omi ẹrọ igbalode, eto ilera alabọde to ba ti igbalode mu, igbanisiṣẹ, aisi ojusaaju ninu iyansipo laaarin ọkunrin ati obinrin, yiyan awọn ọdọ s'ipo adari, aawọn apẹfọn alalopẹ, eto ọrọ aje ati bẹẹbẹẹlọ.
Awọn araalu, nigba ti wọn n sọrọ sọ pe inu okunkun l'awọn wa l'awọn asiko iṣakoso to ti kọja lọ, nitori pe gbogbo awọn nnkan to n fa ipinlẹ naa pada s'ẹyin l'awọn n wo gẹgẹ bi idagbasoke, ti wọn si ni iṣakoso yii lo la wọn loju.
Wọn kani AbdulRazaq ko di gomina ipinlẹ naa l'ọdun 2019 ni, awọn ko mọ ipo ti ipinlẹ naa ko ba wa bayii, nitori pe awọn ijọba to kọja lọ ko jẹ ki wọn mọ ohun to n ṣẹlẹ lagbaye nipa idagbasoke.
Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn iṣẹ akanṣe idagbasoke ti Gomina wọn dawọ le lo ṣee f'oju ri, to si ṣe anfaani pupọ fun wọn, eyi ti wọn n ri lo.
Lara awọn ọtọkulu, alẹnulọrọ ti wọn wa nibi ipade ita gbangba naa ni Sẹneto to n ṣoju ẹkun Iwọ-Oorun Kwara Aṣofin Lọla Ashiru; awọn aṣofin ipinlẹ naa bii Ọnarebu Gbenga Yusuf ati Ọnarebu Razaq Owolabi; Adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ naa tẹlẹ, Onidajọ Raheem Oriloniṣe; Alaga TIC nijọba ibilẹ Ọffa ati Oyun, Ọnarebu Thomas Jare Oladotun ati Ọmọwe Waheed Ọlaitan Ibrahim;
Awọn miran ni aṣoju Ọlọfa tiluu Ọffa, Oloye Yinusa Oyeyẹmi; igbakeji alaga lapapọ fun ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Ọffa, iyẹn Offa Descendants Union (ODU), Alaaji Lateef Bello; Oloye Imaamu Ọffa, Sheikh Muyideen Hussein; Alaga ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi niluu Ọffa, Apostle S.A Akinrẹmi; awọn adari lẹgbẹ oṣelu APC at'awọn miran.
Gomina AbdulRazaq wa fi da gbogbo eeyan loju wi pe oun ṣi n tẹsiwaju awọn akanṣe iṣẹ ti yoo mu ki ipinlẹ naa wa ni ipo akọkọ lori tabili awọn ipinlẹ to wa lorileede Naijiria ni gbogbo ẹka, ati pe oun fẹ ki ipinlẹ naa di ohun ti gbogbo agbaye n pokiki rẹ nipa idagbasoke.
Diẹ ree lara awọn fọto bi eto naa ṣe lọ:
No comments:
Post a Comment