Kii ṣe ọwọ oloṣelu nikan lowo Naijiria wa - Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 10, 2022

Kii ṣe ọwọ oloṣelu nikan lowo Naijiria wa - Amosun


Aṣofin agba Ibikunle Amosun ti sọ pe lotitọ ni pe ọpọ owo to wa lorileede yii, apo awọn oloṣelu lo wa, bo tilẹ jẹ pe kii ṣe gbogbo oloṣelu nikan lo kowo naa dani, bi ko ṣe pe awọn oṣiṣẹ ijọba naa wa lara wọn.

Ibikunle Amosun lo sọrọ naa ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ BBC YORUBA lonii, ọjọ Aje, Mọnde.

"Ṣe ẹ ri ohun ti wọn sọ yii pe ọwọ awọn oloṣelu ni pupọ owo Naijiria wa lọwọ ẹ, otitọ wa nibẹ, amọṣa  bẹẹyẹn kọ lo ṣe ri. Kii ṣe oloṣelu nikan ni owo Naijiria wa lọwọ ẹ, ṣugbọn ṣa, wọn ni oloṣelu lo mọ pupọ ẹ.

"Oṣiṣẹ ijọba naa wa nibẹ. Laipẹ yii la gbọ pe oṣiṣẹ ijọba kan ko nnkankan, bi a ṣe n gbọ ọ l'ọtun l'osi niyẹn. Oloṣelu naa nikan kọ lo wa, wọn ko le da a ṣe, awọn oṣiṣẹ ijọba naa wa nibẹ, ẹlomiran ti ko ṣiṣẹ ijọba naa wa nibẹ. Ṣugbọn bi ori ba ti wọ, gbogbo naa maa wọ ni.

"To ba jẹ pe gbogbo awọn oloṣelu ti wọn ti n ṣe mọ ni, kii ṣe aarẹ nikan, ati awa ti a ti se gomina, awọn to n ṣe lọwọ, ati awọn to jẹ pe ijọba ibilẹ ni wọn ṣe, gbogbo wa naa la ni ẹbi lọwọ. Amọṣa, kii ṣe pe oloṣelu nikan, ṣugbọn awọn oloṣelu ko eyi to pọ ju nibẹ ni."

Bakan naa nigba to n mẹnuba owo ti awọn aṣofin n gba, ti awọn kan sọ pe o pọ ju, ati pe ki iṣẹ aṣofin ma jẹ eyi ti wọn yoo maa ṣe ni gbogbo igba, bi ko ṣe oni ayaba, iyẹn Part Time, Amosun ni:

"Agbajọwọ la fi n sọya, bi gbogbo wa ba fi ẹnuko pe ki iṣẹ aṣofin di ayaba, wọn le ṣe bẹẹ, mo fi ara mọ, bi gbogbo wa ba faramọ. Inu mi si dun pe emi naa ti ni anfaani lati ṣe e ni ọdun 2003 si 2007, mo tun ṣẹṣẹ pada wa lọdun 2019, ti a si n ṣe yii.

"Wọn le sọ pe owo t'awọn aṣofin n gba pọ lotitọ, amọṣa, bi wọn ba fi we awọn ilu yooku, bi ilu Oyinbo, gbogbo nnkan ti awa oloṣelu Naijiria sare lati wa, awọn ti oyinbo ko wa iyẹn mọ. Iṣẹ ti awọn aṣofin n ṣe pọ, iyẹn lo jẹ ko dabi ẹni pe owo ti wọn n fun wọn pọ.

"To ba jẹ pe ijọba wa ti ṣee debi wi pe onikaluku lo niṣẹ ẹ lọwọ ni, ko s'ẹni to fẹ wa tọrọ owo lọwọ oloṣelu kankan."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI