Ile-ẹjọ kotẹmilọrun paṣẹ fun ASUU lati pada s'ẹnu iṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 7, 2022

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun paṣẹ fun ASUU lati pada s'ẹnu iṣẹ


Ile-ẹjọ kotẹmilọrun lorileede yii ti paṣẹ pe ki ẹgbẹ awọn olukọ Academic Staff Union of Universities (ASUU) pada s'ẹnu iṣẹ wọn ni waranṣeṣa, lai fi akoko ṣofo.


Aṣẹ naa waye lẹyin ti ajọ ASUU pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ to paṣẹ pe ki wọn pada sẹnu iṣẹ wọn, ati pe ki wọn fi ori iyanṣẹlodi wọn kọ sẹgbẹ kan, titi digba ti wón yoo fi pe ẹjọ tuntun miran.
 
Ile-ẹjọ naa fun ajọ ASUU ni ọjọ meje gbako lati tun ẹjọ kotẹmilọrun pe, ki wọn si tẹle idajọ to ti kọkọ waye ṣaaju akoko.
 
Bẹ o ba gbagbe, ile-ẹjọ kan ti wọn pe ni National Industrial Court, ti paṣẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan, ọdun yii wi pe ki ajọ ASUU pada sẹnu iṣẹ wọn, ki wọn si so iyanṣẹlodi wọn kọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI