Ijọba Kwara pin ẹgbẹẹgbẹrun iwe kika fawọn akẹkọọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 14, 2022

Ijọba Kwara pin ẹgbẹẹgbẹrun iwe kika fawọn akẹkọọ


Gbogbo awọn akẹkọọ kaakiri ipinlẹ Kwara ni wọn gba ilu ati ijo n'igba ti ijọba ipinlẹ naa pin iwe kika fun gbogbo wọn lati fi ṣe iranlọwọ, paapaa ki eto ẹkọ tubọ ni idagbasoke ati ilọsiwaju alailẹgbẹẹ sii.
 
Iwe kika ti awọn oloyinbo n pe ni Textbooks to le diẹ ni ẹgbẹrun mejidinlaadọrin, 68,280 ni ijọba Kwara pin f'awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ.
 
Lara awọn ileri ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe wi pe oun ko nii fi ọmọ kankan silẹ tabi ya ọmọ kankan sọtọ lati ni anfaani si awọn ohun elo to le mu ki wọn kawe tabi kẹkọọ, to si ni gbogbo wọn pata ni wọn yoo lafaani si awọn nnkan ikẹkọọ.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq nibi to ti n ṣiṣọ loju eegun bi wọn ṣe pin awọn iwe naa lonii, ọjọ Ẹti, Furaide, eyi to waye niluu Shao, ijọba ibilẹ Moro, o ṣalaye pe awọn akẹkọọ ipele kẹrin, ikarun-un ati ikẹfa ni awọn iwe naa wa.

AbdulRazaq ti igbakeji rẹ, Ọgbẹni Kayọde Alabi ṣoju fun jẹ ko di mimọ pe idunnu nla lo je wi pe gbogbo igbesẹ ti ijọba ipinlẹ naa n gbe lati ni ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu ajọ to n ṣe iranwọ fun eto ẹkọ, iyẹn Universal Basic Education Commission (UBEC) lo ti n so eso rere.
 
Kayọde Alabi ni igba akọkọ ree ti ipinlẹ Kwara yoo maa jẹ anfaani ajọ UBEC, to si ni ere nla to pọ ni fun wọn lati jẹ ki ọjọ iwaju awọn ogowẹẹrẹ daju nipa ikẹkọọ to ye kooro.
 
O wa rọ awọn akẹkọọ naa lati gbajumọ eto ẹkọ wọn, ki wọn si rii daju pe wọn n mu awọn iwe ti wọn ṣẹṣẹ gba lo, lọna ti yoo mu ki wọn kẹkọọ ti yoo ba ti igbalode mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI