Ijọba Kwara fi itan tuntun balẹ, wọn ko ọgọsan akẹkọọ lọ sile ẹkọ wọn lọfẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 31, 2022

Ijọba Kwara fi itan tuntun balẹ, wọn ko ọgọsan akẹkọọ lọ sile ẹkọ wọn lọfẹ


Ko din ni ọgọsan akẹkọọ ile ẹkọ fasiti ti ijọba ipinlẹ Kwara ti da pada si ile ẹkọ wọn lọfẹẹ, léyin ti ajọ ASUU kede wi pe ki iṣẹ bẹre pada.
 
Gbobo awọn akẹkọọ ti wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kwara, ti wọn n kẹkọọ ni ariwa orileede yii la gbọ pe ijọba gbe awọn bọọsi bọginni-bọginni kalẹ lati fi ko gbogbo wọn pada sile ẹkọ.
 
Igba akọkọ ree ninu itan ti ijọba maa gbe iru igbesẹ bayii, eyi to mu k'awọn araalu, paapaa awọn ọdọ maa gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.

Bọọs nla-nla elero mejidinlogun ti ko din ni aadọta la gbọ pe ijóba Kwara ṣeto rẹ lati da gbgbo awọn akẹkọọ pada sile ẹkọ wọn ni Ariwa ilẹ Naijiria, iyẹn lonii, ọjọ Aje, Mọnde.

Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna fọọ eto ẹkọ agba, Ọmọwe Alabi Afees Abọlọrẹ ṣalaye pe lati le ṣe iranwọ f'awọn obi kaakiri ipinlẹ naa, lo fa a ti ijọba fi gbe iranwọ dide fun gbogbo akẹkọọ wọnyi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI