Ko din ni ẹgbẹrun mọkanlelogun, 21,750 araalu kaakiri ipinlẹ Kwara, ti wọn ti jẹ anfaani eto aabo ilera ọfẹ ti a mọ si Health Insurance.
Ọdun kan gbako la gbọ pe awọno araalu naa yoo fi jẹ anfaani eto ilera ọfẹ yii, eyi ti ijọba ṣagbatẹru ẹ lati le jẹ ki awọn eeyan jẹ mudunmudun eto oṣelu awaarawa.
Lasiko yii, ilu Abuja to jẹ olu-ilu Naijiria ṣi n gbe sadankata fun ipinlẹ Kwara, lori bi wọn ṣe n lewaju ninu eto idagbasoke lẹka ilera, paapaa f'awọn araalu.
Ipinlẹ Kwara wa lara awọn ipinlẹ ti kii fi ọrọ ilera araalu ṣere rara, gẹgẹ bi a ti gbọ.
Yatọ si eyi, a gbọ pe awọn mọkandinlọgbọn ọmọ ipinlẹ Kwara ni ijọba ipinlẹ naa ṣagbatẹru fun lati jẹ anfaani eto ilera labẹ ijọba apapọ orileede Naijiria, labẹ eto ti wọn pe ni FG-funded Basic Health Care Provision Fund (BHCPF), ti a si gbọ pe awọn to le ni ẹgbẹrun mọkanlelaadọta 51,750 ni wọn yoo jẹ anfaani yii laaarin ọdun 2022 si 2023.
Nibi ifilọlẹ ipele keji eto yii to waye lọjọ Ẹti, Furaide, niluu Ilọrin, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe wi pe awọn ti ko owo to pọ le ẹka eto ilera, nipa rira irinṣẹ eto ilera igbalode, ti yoo f'ọkan araalu balẹ, lati ma ṣe maa sa kaakiri.
No comments:
Post a Comment