Ẹ ma ṣe gbe gbogbo igbagbọ yin le Ọlọrun - Kiddwaya BBNaija - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 16, 2022

Ẹ ma ṣe gbe gbogbo igbagbọ yin le Ọlọrun - Kiddwaya BBNaija


Ọkan lara awọn ọmọ inu ile ẹlẹgbọn agba ti a mọ si Big Brother Naija, iyẹn BBNaija, Terseer Kidd Waya, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Kiddwaya, ti gba gbogbo ọmọ orileede Naijiria lamọran lati ma ṣe maa gbe gbogbo igbagbọ wọn le Ọlọrun.

 
Kiddwaya lo sọrọ naa lori ikanni ayelujara ti Twitter laipẹ yii, to si ni ki awọn eeyan nigbagbọ ninu ara wọn ju Ọlọrun lọ.
 
O ni Ọlọrun ti fun awọn eeyan ni agbara lati maa nigbagbọ ninu ara wọn, nitori naa ni wọn ko ṣe gbọdọ maa gbẹkẹle Ọlọrun ju ni gbogbo igba.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ẹ gbiyanju lati ma ṣe maa gbe igbagbọ yin to pọ s'ọdọ Ọlọrun. O ti fun wa ni agbara lati nigbagbọ ninu ara wa."
 
Bakan naa nigba to n fi baba rẹ we awọn miran, o ni ki gbogbo awọn ti baba wọn ko lowo to baba oun tẹpa mọ iṣẹ gidigidi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI