Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ baale ile meji kan ti wọn lu iyaale ile ni jibiti miliọnu meje aabọ naira lori ẹtanjẹ lati ṣiṣẹ itusilẹ fun un.
Bo tilẹ jẹ pe agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa, Bẹnjamin Hundeyin ko ṣalaye kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ, ṣugbọn sibẹ, o ni obinrin naa ni aṣiri tu si lọwọ lẹyin ti wọn ti gba owo naa lọwọ ẹ.
Hundeyin ni loju ẹsẹ ni obinrin naa ti gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti pe awọn ọkunrin meji kan ti lu oun ni jibiti owo.
Nibẹ l'awọn ọlọpaa ti sọ pe ki obinrin naa tun pe ipade pẹlu wọn lati gba owo miran, ti awọn naa si wa. Loju ẹsẹ lọwọ palaba wọn ti segi.
Hundeyin fi ye wa pe iwadii ṣi n lọ lọwọ.
No comments:
Post a Comment