Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ ọ di mimọ pe k'awọn araalu maa wa ni ifura ni gbogbo igba, nitori ayipada oju ọjọ to n ṣẹlẹ loore-koore lo n fa omiyale to n ṣẹlẹ lẹnu ọjọ mẹta yii.
Wọn ni b'awọn araalu ṣe n lo awọn nnkan ajogunba bii ilẹ, igi at'awọn nnkan miran lo fa a ti oju ọjọ fi n yi pada, eyi to n ṣakoba fun omiyale.
Kọmiṣanna fọrọ eto ayika ati agbegbe Ọnarebu Banigbe Rẹmilẹkun Oluwatobi lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii, to si ni iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti n ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe wọn dẹkun gbogbo nnkan to le fa omiyale laarin ilu, eyi ti yoo ṣakoba fun ẹmi ati dukia araalu
O ni ijọba ti bẹrẹ sii gbẹn awọn odo ati gọta to ti n di odo, ti wọn si ti n ṣe awọn atunṣe ti yoo maa jẹ ki omi ṣan lọ sibi to yẹ lai si idiwọ ati idena.
Lara wọn ni odo Asa, at'awọn miran.
Bẹẹ lo gbawọ araalu lamọran lati ṣọra nipa lilo awọn kọta aarin ilu, to si ni ki wọn dẹkun dida idọti s'awọn ibi ti omi n gba kọja, ko ma ba a ṣakoba fun wọn.
No comments:
Post a Comment