Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba awọn ọlọ ibi mẹta ọtọọtọ lonii, ọjọ Aje, Mọnde yọ lori ayẹyẹ ibi wọn, to si n ki wọn ku oriire, bẹẹ lo tun gbadura fun wọn.
Biṣọọbu ijọ Afrika, Biṣọọbu Sunday Adewọle, ẹni to tun jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ awọn Kristẹẹni, iyẹn CAN n'ipinlẹ naa; Alaga ẹgbẹ oṣelu APC n'ipinlẹ naa, Oloye Sunday Fagbemi ati gbajugbaja olokoowo nni, Hajia Bola Shagaya ni Gomina AbdulRazaq n ki ku oriire ayẹyẹ ọjọ ibi wọn.
Niniu atẹjade ti Gomina gbe jade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, o ni awọn mẹtẹẹta yii ni wọn n ko ipa rere to jọju ninu idagbasoke ati eto aabo ipinlẹ Kwara, to si lo di dandan lati ba wọn yọ ayọ ayẹyẹ ọjọ ibi wọn.
Ni ti Biṣoọbu Adewọle to n ṣayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹtadinlọgọta, 57, AbdulRazaq sọ pe oun n ṣoju gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lati ki ojiṣẹ Ọlọrun naa to n fi gbogbo igba kede alaafia ati iṣọkan laaarin awọn ẹya, paapaa awọn ẹlẹsin yooku.
Bakan naa, ni ti alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara, Oloye Sunday Fagbemi, AbdulRazaq ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi akikanju to fi ti ọrọ ẹgbẹ at'awọn ọmọ ẹgbẹ s'ọkan, to si tun jẹ awokọṣe rere lawujọ.
Siwaju sii, ni ti Hajia Bọla Shagaya, AbdulRazaq ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bi ẹni to n mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ipinlẹ naa, to si jẹ awokọṣe f'awọn obinrin l'ẹka eto ọrọ aje ati okoowo.
O wa gbadura ẹmi gigun ati alaafia fun gbogbo wọn.
No comments:
Post a Comment