Gbogbo awọn ọdọ ilu Orile Ilawọ, Alagbagba ati agbegbe rẹ ni wọn ti f'ontẹ lu Ọba Oluṣẹgun Alex Macgregor gẹgẹ bi Ọba tuntun ti ijọba ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ yan fun wọn.
Ọba Macgregor ni awọn oloye to ṣoju afọbajẹ dibo yan nibi eto idibo to waye niluu Ẹlẹgunmẹfa laipẹ yii.
Nigba ti wọn n ṣe abẹwo si Ọba tuntun naa, awọn ọdọ naa ti Kọmureedi Fatai Balogun to jẹ olori ọdọ lẹwaju wọn ni wọn ti sọ ẹdun ọkan wọn, lara eyi ti wọn lo n fi iya jẹ wọn.
Awọn ọdọ naa jẹ ko di mimọ pe awọn oloye ilu Ilawọ ti ta gbogbo ilẹ ilu tan f'awọn ajoji, ti wọn ko si ronu nipa idagbasoke ati ilọsiwaju ilu Ilawọ.
Koda, wọn l'awọn oloye naa ko ronu nipa ọjọ iwaju awọn ogowẹẹrẹ, paapaa awọn ọdọ, eyi to mu ki wọn maa ta gbogbo dukia ati awọn nnkan amuṣọrọ ilu ti wọn sọ pe ko ba oju mu to.
Wọn l'awọn ko si ninu awọn to n lọ kaakiri lati fẹhonu han wi pw awọn ko fẹ Ọba Macgregor gẹgẹ bi olori wọn, nitori pe awọn mọ ohun to tọ si wọn, ati pe awọn ko le jẹ ki awọn to ma maa ta ilẹ ati dukia ilu f'awọn ajoji.
Wọn ni pupọ ninu awọn ti wọn n ko kaakiri lati fẹhonu han ni wọn kii ṣe ọmọ bibi ilu Ilawọ ati Alagbagba, bi ko ṣe pe ṣe ni wọn lọ fi owo ya awọn eeyan naa.
Nigba to n fesi, Ọba tuntun naa sọ pe igba ọtun ti de bayii, nitori pe iṣakoso oun yoo mu ilọsiwaju ba ilu, nitori pe awọn akanṣe iṣẹ loun yoo dawọ le.
Siwaju sii ni Ọba Macgregor fi kun ọrọ rẹ pe bo tilẹ jẹ pe kii ṣe akọkọ ree toun yoo maa ṣe awọn nnkan to n mu idagbasoke ba ilu, to si ni awọn ipa to jọju loun ti mu ba ilu Ilawọ ati agbegbe rẹ
Ọba Macgregor wa rọ awọn ọdọ naa lati fọwọsowọpọ pẹlu oun, ki wọn si gba ifẹ, alaafia ati iṣọkan laaye laaarin ara wọn, eyi to le mu ilọsiwaju ba ilu naa.
No comments:
Post a Comment