Kani kii ṣe ori to ko Ifẹnuga Ọlayinka yọ ni, boya ni wọn ko ba ti da ẹmi rẹ legbodo lẹyin ti wọn ba jii gbe, ti wọn si tun gba owo lọwọ ẹ.
Ọlayinka la gbọ pe o sare gba teṣan ọlọpaa ti ẹkun Igbẹba to wa n'ipinlẹ Ogun lọ lati ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lori foonuu to n lo.
A gbọ pe atẹjiṣẹ kan lo wọle sori foonu Ọlayinka wi pe ko san miliọnu marun-un naira si akanti ti wọn fi ranṣẹ sii, tabi ki wọn jii gbe to ba kọ lati san owo naa. O ni ẹni to fi atẹjiṣẹ naa ranṣẹ pe orukọ ara rẹ ni "Killer Vagabond of Africa".
Pẹlu ibẹrubojo la gbọ pe Ọlayinka fi gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti wọn si l'awọn ọlọpaa gan-an ko fi ọrọ ọhun falẹ rara, ti wọn fi bẹrẹ iṣẹ iwadii.
Iwadii naa lo gbe wọn de ilu Anambra, nibi ti wọn ti lọ gbe Peter Nse, ọmọ ọdun mẹrinlelogun ati Chuckwuma Nwobodo, ẹni ọdun mejidinlaadọta.
Awọn mejeeji ti ọwọ tẹ yii lo pada tu aṣiri bi ọwọ ṣe pada tẹ Michael Umanah, ọmọ ọgbọn ọdun niluu Agọ-Iwoye.
Lẹyin ti ọwọ tẹ awọn mẹtẹẹta la gbọ pe awọn ọlọpaa f'oju wọn han fun Ọlayinka ti wọn fẹẹ jigbe, tiyẹn si loun mọ wọn daadaa. Ọlayinka ṣalaye pe oun ṣẹṣẹ le awọn mẹtẹẹta danu nileeṣẹ oun ni, nitori ẹsun aṣemaṣe to fi kan wọn.
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lẹkunrẹrẹ, ko to di pe wọn f'oju wọn ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment