Awọn alakoso ẹgbẹ eleto aabo Fijilante lorileede Naijiria, iyẹn Vigilante Group of Nigeria, VGN ti sọ ọ sita wi pe awọn kan ti n palẹmọ lati fi orukọ ẹgbẹ naa lu awọn araalu, paapaa awọn oloṣelu ni jibiti, ti wọn si ni ki wọn fura si wọn.
Ninu atẹjade ti alukoro ẹgbẹ naa, ACG Igho Akeregha, fi sita l'Ọjọru, Wẹsidee to kọja, o ni awọn to n gbero lati ṣe ipagọ niluu Abuja l'ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa ti a wa yii, wọn kii ṣe ojulowo ọmọ ẹgbẹ naa, bi ko ṣe pe wọn fẹẹ fi orukọ ẹgbẹ naa lu jibiti ni.
Akeregha ni ẹgbẹ fijilante kan ṣoṣo to wa ni Ajagunfẹyinti Umar Bakori jẹ alakoso wọn, ti ko si si ẹgbẹ miran mọ.
O ni erongba awọn to gbe ayederu ipagọ ọhun kalẹ kan fẹẹ lo lati lu awọn araalu ni jibiti lasan ni, to si ni The Velodrome to wa ninu papa iṣere MKO ni wọn ti fẹẹ ṣe e, pẹlu akori ti wọn pe ni 'Small Arms and Light Weapons proliferation and it's threat to Nigeria's internal security'.
Bakan naa lo sọ pe fọnran kan to n lọ kaakiri ori ayelujara, eyi ti ko ni orukọ ninu tun sọ pe Gomina Yahaya Bello ti ipinlẹ Kogi ni wọn fẹẹ fi ṣe alaga ipagọ naa, to fi mọ awọn ọba at'awọn ajagunfẹyinti gẹgẹ bi alejo wọn.
O wa ni awọn alaṣe agba fun VGN gbọ pe oṣiṣẹ ologun ti wọn ti le danu nigba kan, ẹni ti wọn pe orukọ rẹ ni Usman Mohammed Jahun lo n pe ara rẹ ni ọga agba pata fun VGN, lati maa fi lu jibiti kaakiri, to si ni k'awọn araalu ṣọra wọn fun un.
Akeregha tẹsiwaju pe oun gba awọn araalu lamọran lati maṣe ni ohunkohun ṣe pẹlu Usman Mohammed Jahun, nitori pe ṣe ni wọn lee danu lori ẹsun biliọnu kan naira to jẹ owo VGN, eyi ti ajọ EFCC n ṣe iwadii rẹ lọwọ.
"Usman Mohammed Jahun ko ni iwe ẹri, ohun idanimọ ati aworan idanimọ ẹgbẹ VGN lọwọ, sibẹ, o ṣi n gbe eto kalẹ lorukọ ẹgbẹ naa lai maa fi lu jibiti pẹlu apo ifowopamọ tiẹ gangan, ti kii ṣe ti ẹgbẹ.
"A ti fi ẹsun iwa jibiti rẹ to awọn ileeṣẹ eleto aabo leti, o si sare gba ile-ẹjọ lọ, lati wa aabo funra rẹ, bo tilẹ jẹ pe a ṣi n duro de idajọ ile-ẹjọ ọhun.
"VGN rawọ ẹbẹ si ọga ọlọpaa pata lorileede yii, ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS lati ṣe iwadii lẹkunrẹrẹ nipa Usman Mohammed Jahun to fẹ ki VGN ṣiṣẹ fun égbẹ oṣelu All Progresives Congress, (APC), eyi to tako ofin ati alakalẹ ẹgbẹ naa."
No comments:
Post a Comment