Awa la ji baba ẹni ogoji ọdun gbe, a paa lati fi ṣetutu owo fun iṣẹ 'Yahoo-Yahoo' ti a n ṣe ni - Odeh ati Idowu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 10, 2022

Awa la ji baba ẹni ogoji ọdun gbe, a paa lati fi ṣetutu owo fun iṣẹ 'Yahoo-Yahoo' ti a n ṣe ni - Odeh ati Idowu


Beeyan ba wa nibi ti gendekunrin meji yii, Friday Abinya Odeh, ọmọ ọdun mọkanlelogun ati Poso Idowu, toun jẹ ọmọ ogun ọdun ti n ka boroboro lori bi wọ ṣe pa Abdullahi Azee, ẹni ogoji ọdun danu lati fi ṣetutu owo, yoo mọ pe ọdaju pọmbele ni wọn.
 
Ọjọ kẹsan, oṣu kẹfa, ọdun yii la gbọ pe wọn lọ fi iṣele bi Azeez ṣe poora to ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Owode Ẹgba lolobo. Wọm ni ọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa ni Azeez to n gbe lagbegbe Kọbapẹ jade nile, ti ko si pada sile.
 
Wọn ni gbogbo bi wọn ṣe n pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ ni ko lọ, ti wọn ko si mọ ibi ti wọn le wa a si. Gbogbo ibi ti a gbọ pe wọn fura si wi pe o le wa ni wọn ti lọ wo o nibẹ, ṣugbọn to pada ja si pabo.
 
Iroyin naa lo tẹ ọga ọlọpaa, CP Lanre Bankọle, leti, tiyẹn fi paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lati mọ ibi ti Azeez wọlẹ si.
 
Iwadii naa lo gbe wọn de ibi ti Friday Abinya Odeh n gbe l'ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsanm ọdun yii, nibi ti wọn ti ṣawari kaadi ipe 'Sim Card', to jẹ ti oloogbe naa.
 
Friday lo pada jẹwọ pe Poso Idowu l'awọn jọ mọ nipa bi oloogbe naa ṣe poora.
 
Nigba t'awọn mejeeji n jẹwọ f'ọlọpaa, wọn ni ọjọ kẹjọ l'awọn ji Azeez gbe, ti wọn si pa a sinu oko lagbegbe Kọbapẹ ni nnkan bi aago meje aabọ irọlẹ ọjọ naa.
 
Lẹyin ti wọn pa a tan, ni wọn l'awọn pin ẹya ara rẹ si wẹwẹ, ko to di pe wọn yọ eyi ti wọn nilo ninu ẹya rẹ, ti wọn si gbe e lọ fun babalawo kan ti wọn pe ni 'Arab Money', ẹni ti wọn sọ pe wọn pade lori ikanni ayelujara ti fesibuuku.
 
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n sọ pe awọn ko tii mọ ibi ti awọn mejeeji naa ju oku Azeez to ku si, nitori pe awọn naa ko le sọ pato ibi ti oku yooku naa wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI