Aderinokun ni ojulowo oludije sipo ile igbimọ aṣofin labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun - Ile ẹjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 6, 2022

Aderinokun ni ojulowo oludije sipo ile igbimọ aṣofin labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun - Ile ẹjọ


Ile ẹjọ giga apapọ to fikalẹ siluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ti paṣẹ wi pe Oloye Olumide Aderinokun ni oludije sipo ile igbimọ aṣofin agba orileede yii lati aarin gbungbun ipinlẹ naa, iyẹn labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.

Onidajọ O. O. Oguntoyinbo, nigba to n wọgile ẹjọ ti alatako Aderinokun, Dada Kọlawọle Ẹnitan pe lati tako bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe yan an gẹgẹ bi oludije sipo aṣofin lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹta, ọdun yii ni ẹgbẹ oṣelu naa ṣe eto idibo abẹle ni gbọngan ile ikawe Oluṣẹgun Ọbasanjọ, iyẹn Olusegun Obasanjo Presidential Library to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Nibẹ ni wọn ti dibo yan Aderinokun gẹgẹ bi ọmọ oye ti yoo dije du ipo naa.

Lẹyìn eto idibo abẹle ọhun ni Dada Kọlawọle Ẹnitan pe ẹjọ wi pe bi wọn ṣe yan Aderinokun ko tọna, ati pe oun lẹni ti ẹgbẹ naa ni lerongba lati fa kalẹ.

Onidajọ Oguntoyinbo nigba to n da ẹjọ naa nu, o ni ọna ti wọn gba pe ẹjọ naa kọ ba ofin mu, nitori pe ko si amofin kankan to bu ọwọ lu.

Nigba toun naa n sọrọ lẹyin ti ile ẹjọ da ẹjọ naa nu, Oloye Aderinokun sọ pe idajọ naa jẹ eyi to foju han pe ko sẹni to le da ile ti Ọlọrun ti kọ wo, nitori pe ohun araalu ni yoo di mimuṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI