Kayeefi nla gba a ni ọrọ gendekunrin, ọmọ ọdun mẹtalelogun kan, Abidemi Oguntuyi, ṣi n jẹ lori bo ṣe gun olulaja oun ati ẹgbọn rẹ pa niluu Akugba Akoko, ipinlẹ Ondo.
AWIKONKO gbọ pe ile kan naa ni Abidemi ati ẹni to gun pa, baale ile ẹni ogoji ọdun jọ n gbe.
Ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan-an to ṣẹṣẹ kọja yii la gbọ pe ija bẹ silẹ laaarin Abidemi ati ẹgbọn rẹ ninu ile, ti wọn si l'awọn eeyan gbiyanju lati la wọn.
Nibi ti ija naa ti n kọja oju t'awọn eeyan fi n wo, la gbọ pe Abiye Friday jade ninu yara tiẹ lati la wọn. Ibi to ti n gbiyanju lati la awọn mejeeji yii ni wọon sọ pe Abidemi ti fa ọbẹ yọ, to si fi gun Abiye lọrun titi to fi ku.
Loju ẹsẹ la gbọ pe o ti fẹẹ na papa bora, ṣugbọn t'awọn eeyan sare mu mọlẹ, ti wọn si lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.
Nigba ti wọn f'oju Abidemi ba ile ẹjọ, Majisireeti to wa niluu Akurẹ, Onidajọ D. S Ṣekoni paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi pamọ s'ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo tun pada waye l'ọjọ keje, oṣu yii.
Agbefọba Simon Wada to tako Abidemi niwaju ile ẹjọ sọ pe nnkan bi aago mọkanla aarọ ni Abidemi gun Abiye pa nibi tiyẹn ti n la wọn, eyi to lo tako iwe ofin ọdaran ti abala 319 ati 355, tipinlẹ Ondo Cap. 37 Vol. II Law of 2006.
O wa rọ ile ẹjọ lati fi Abidemi pamọ si ọgba ẹwọn Olokuta titi ti igbẹjọ yoo fi waye.
No comments:
Post a Comment