Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe gbogbo awọn ti ijọba apapọ orileede yii da lọla lati ipinlẹ naa ni wọn kaju oṣuwọn, ati pe wọn lẹtọọ si awọn aami ẹyẹ tuntun naa.
Awọn ti ko din ni mọkanla lati ipinlẹ Kwara la gbọ pe wọn gba aami ẹyẹ ti ijọba apapọ labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, gẹgẹ bi atẹjade ti ileeṣẹ to n ri sọrọ akanṣe iṣe ati ohun to jẹ mọ ọrọ ijọba, iyẹn Federal Ministry of Special Duties and Inter-Governmental Affairs fi sita.
Lara awọn to gba aami ẹyẹ idalọla naa lati ipinlẹ Kwara ni Aarẹ ile-ẹjọ kotẹmilọrun lorileede yii tẹlẹ, Onidajọ Ayọ Salami, to gba aami ẹyẹ CFR; Adajọ agba nipinlẹ Kwara, Onidajọ Sulyman Durosinlọhun Kawu, toun gba aami ẹyẹ OFR; Adajọfẹyinti nile ẹjọ kotẹmilọrun ti Sharia, Onidajọ Idris Abdullahi Haroon, toun naa gba oye OFR; ati ọga agba pata lẹka eto aabo oju popona lorileede yii, iyẹn Federal Road Safety Corps (FRSC), Ọmọwe Bọboye Oyeyẹmi, to gba aami ẹyẹ OFR.
Awọn yooku ni minisita fọrọ et iroyin ati aṣa, Alaaji Lai Mohammed, CON; gbajugbaja ọjọgbọn lẹka eto iwosan, Ọjọgbọn Wale Suleiman, CON; Grand Mufti tiluu Ilọrin, Sheikh Suleiman Faruq Onikijipa, OON; Imaamu agba fun mọṣalaṣi aarin gbungbun Fouad Lababidi to wa l'Abuja, Sheikh Muhammẹd Tajudeen Adigun, OON; ati Alaaji Kamọru Ibitoye Yusuf, MON.
Yatọ si awọn wọnyi, wọn tun fi aami ẹyẹ MON naa da gbajugbaja agbabọọlu fun ilẹ Naijiria nigba kan ri, ẹni to ti d'oloogbe, Rashidi Yẹkeen ati CSP Benedict Okoh Ajide, ọlọpaa toun naa ti f'ilẹ ṣaṣọbora.
No comments:
Post a Comment