Lati saami ayajọ ọjọ awọn olukọ kaakiri agbaye, eyi to waye l'Ọjọru, Wẹside, ọsẹ yii, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti da awọn olukọ ti ko din ni mọkandinlọgọta lọla pẹlu ẹbun loriṣiriṣi.
Ipinlẹ naa ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fi ẹmi imọriri han si gbogbo awọn olukọ patapata, lori ipa ti wọn n ko lẹka eto ẹkọ, paapaa bi wọn ṣe n fi iṣẹ wọn si ipo akọkọ.
Nibi ayajọ naa ni Gomina ti ṣeleri wi pe gbogbo awọn ọrọ ajọsọ to ti wa nilẹ tipẹ loun yoo gbe yẹwo, toun yoo si tete ṣiṣẹ lori rẹ, nitori pe ipa ti awọn olukọ n ko ninu idagbasoke orileede ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.
No comments:
Post a Comment