Sẹnetọ Ibikunle Amosun to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin agba orileede yii ti sọ pe ko si nnkan to le mu k'oun tẹle Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ninu eto idibo to n bọ lọna yii.
Amosun sọ pe bo tilẹ jẹ pe Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu loun n tẹle lati di aarẹ orileede Naijiria lọdun 2023, sibẹ o ni iyẹn ko sọ pe koun tẹle Gomina Dapọ Abiọdun lati ṣe saa keji.
Lonii, ọjọ Aje, Mọnde ni Gomina Amosun sọrọ naa nile ẹ to wa niluu Abẹokuta, nibi to ti gba ikọ akọroyin BBC YORUBA lalejo.
Amosun nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe oludije s'ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC, Biyi Ọtẹgbẹyẹ loun maa ṣiṣẹ lati de ipo gomina l'ọdun 2023.
O ni wi pe oun wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC pẹlu Gomina Dapọ Abiọdun, iyẹn ko ni koun ṣagbatẹru ẹ lati pada sipo naa lẹẹkeji.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
"Mo le fi da gbogbo eeyan loju pe nipa ti ipo Aarẹ, ati ọtun, ati osi, ẹnikan ṣoṣo ni gbogbo wa n ṣiṣẹ fun. Bi emi ṣe ro o niyẹn, lọkan t'ẹmi. Mo nigbagbọ pe gbogbo wa la jọ ro o pe ibi kan naa la jọ n ṣiṣẹ si.
"Ṣe ẹ ri ti ibo gomina, ọtọọtọ niyẹn. A ko fi iyẹn bo f'ẹnikẹni. Emi ko fi si ibi ti ẹni tibi yii fi si. Lori ipo gomina, mi o si ni ibi ti ẹgbẹ oṣelu APC yii wa. Ẹni ti ko ba fẹ ipalara fun eeyan , l'ẹyan maa f'ẹju fun.
"Ajọjẹ ko si dun bi ẹnikan ko ni. Mo si sọ fun un yin ṣaaju pe bi mi o ba tii dele laaarin ọsẹ kan, ara mi ko tii balẹ. Ile ti mo n wa, nitori ti mo ba wa, mo n ri awọn eeyan deba ni. Gbogbo awọn eni yii, latigba ti a ti wọ ọ, gbogbo wọn ni wọn duro.
"Ti gbogbo wọn ba wa duro, ti wọn ko wa ṣe daadaa fun awọn to ti ṣe wahala f'ẹgbẹ yii, ko si bi wọn ṣe fẹẹ sọrọ APC n'ipinlẹ Ogun, mo le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe awa la ṣe e, Ọlọrun lo si fun wa ṣe.
"Ko wa le di pe ki eeyan kan wa de, ko wa fẹẹ pa wọn ti, rara, wọn kii ṣe bẹẹyẹn. Awa kọ ni Ọlọrun. Emi kii ṣe nnkan t'emi ni kọọrọ, rara, mi o fi bo. Wọn maa n sọ pe gbogbo aṣọ kọ la n sa l'oorun, ṣugbọn emi maa n sọ fun wọn pe ki wọn jẹ ka sa eleyii l'oorun.
"Ni ti olori orileede, ti mi o ba nii ṣe, maa sọ pe mi o ṣe, eleyii ti a si n ṣe, gbogbo wa la n ṣe. Ni ti gomina, emi ko ba wọn si nibẹ, mo si mọ pe awọn ti a jọ n ṣe naa ko ṣe. Wọn n ṣe ti wọn, awa naa n ṣe ti wa, a ko si fi bo.
"Biyi Ọtẹgbẹyẹ ti ẹgbẹ oṣelu ADC ni mo to si lẹyin."
No comments:
Post a Comment