Wọn fẹẹ ba mi lorukọ jẹ ni o - Olomu tilu Omu-Aran pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 15, 2022

Wọn fẹẹ ba mi lorukọ jẹ ni o - Olomu tilu Omu-Aran pariwo sita


Olomu tilu Omu-Aran, Ọba Abdulraheem Adeoti ti pariwo sita wi pe awọn ọbayejẹ kan ni wọn fẹẹ ba oun lorukọ jẹ, nitori toun ko mọ nnkankan nipa ọhun ti wọn n pe kaakiri nipa oun.
 
Ọba Adeoti, ẹni to tun jẹ Ologbomọna ti ilẹ Igbomina kaakiri sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa ohun naa ti wọn n gbe kiri pe oun ti paṣẹ pe ki ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ma ṣe wa polongo idibo niluu Omu-Aran.

Ninu atẹjade ti Kabiyesi naa gbe jade lorukọ akọwe ẹgbẹ idagbasoke Omu-Aran, Ọgbẹni Ọlayinka Owolẹwa l'ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii sọ pe oun ko pa aṣẹ kankan wi pe ki ẹgbẹ oṣelu kankan ma ṣe de ilu naa lati polongo idibo.

Kabiyesi naa sọ pe oun kii ṣe oloṣelu, bi ko ṣe olori ilu ti ijọba f'ọwọ si, fun idi eyi, o l'awọn ọta oun ni wọn n ṣagbatẹru ohun naa lati sọ pe ki ẹgbẹ oṣelu APC ma ṣe wa polonogo ibo.
 
Kabiyesi loun ti paṣẹ pe ki igbimọ Olomu dide lati ṣe iwadii awọn to wa nidii ohun naa, ki wọn si fi wọn jofin, labẹ ofin orileede yii, nitori iwa ọdaran gba a ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI