Wọ́n dá ẹjọ́ ikú fún ẹ̀gbọ́n àti àbúrò l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 14, 2022

Wọ́n dá ẹjọ́ ikú fún ẹ̀gbọ́n àti àbúrò l'Ékòó


Ile ẹjọ ẹsun to ṣara ọtọ, iyẹn Special Offences Court to wa ni Ikẹja, ipinlẹ Eko ti ju ẹgbọn ati aburo si ẹwọn gbere pẹlu iṣẹ aṣekara.

Genesis Ezebong ati aburo rẹ, Michael Ezebong ni awọn mejeeji ti ile ẹjọ pàṣẹ pe ki wọn lọ lo eyi to ku ni igbesi aye wọn lọgba ẹwọn.

Yatọ si awọn mejeeji yii, ile ẹjọ tun ju Ikade Moses to jẹ ọrẹ wọn naa si ẹwọn gbere pẹlu iṣẹ aṣekara.

Ẹsun idigunjale ati ilọnilọwọgba ni ijọba ipinlẹ Eko fi kan awọn mẹtẹẹta niwaju ile ẹjọ ti Onidajọ Oluwatoyin Taiwo lewaju ẹ.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Oluwatoyin Taiwo sọ pe awọn ẹri to wa niwaju oun kọja nnkan ti wọn le fọwọ bo, nitori pe otitọ pọmbele ni.

Ọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, ọdun 2020 la gbọ pe wọn kọkọ fi oju wọn ba ile ẹjọ, ko to di pe wọn bẹrẹ igbẹjọ lẹkunrẹrẹ lọjọ kọkanla, oṣu kin-ni-in, ọdun 2022 yii.

Agbefọba, Ọmọwunmi Bajulaye nigba to n ṣalaye fun ile ẹjọ, o ni ọjọ kẹtala, oṣu kin-ni-in, ọdun 2019 ni awọn mẹtẹẹta lọ digunjale lojule kejilelogun, opopona Ikorodu, agbegbe Palm Groove, l'Ekoo.

Bojulaye sọ pe ada, ṣọbiri, at'awọn nnkan ija oloro miran ni wọn ko lọ fi kale ọhun. Daniel ni orúkọ ẹni naa ti wọn ja lole.

Kọmputa alagbeeka meji, goolu, foonu, kamẹra, bata ti wọn fi n gba bọọlu, ati foonu miran to jẹ ti Titilọpẹ Akeredolu ni wọn digun gba nigba naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI