Itan nla tuntun ni Wolii Elijah Babatunde Ayọdele to jẹ olori ati alaṣẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church to wa niluu Eko fẹẹ fi balẹ bayii, pẹlu bo ṣe fẹẹ bẹrẹ si i kọ ṣọọṣi tuntun ti yoo gba to ero ti ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọta ọmọ-ijọ.
Ẹgbẹlẹgbẹ ẹgbẹrun miliọnu naira la gbọ pe wọn fẹẹ fi kọ ṣọọṣi tuntun naa si agbegbe Oke-Afa, iyẹn nibi ti olu ijọ naa wa tẹlẹ.
A gbọ pe ki i ṣe pe wọn fẹẹ kọ ṣọọṣi ọhun lati fi figagbaga pẹlu awọn ṣọọṣi nla-nla miran kaakiri agbaye, bi ko ṣe pe erongba naa jade nipa bi awọn ọmọ ijọ naa ṣe n fi ojoojumọ pọ si, ti ṣọọṣi naa ko si fẹẹ gba awọn eeyan mọ.
Ọpọ igba ni Wolii Ayọdele ti sọ nipa bi wọn ṣe bẹrẹ ijọ naa pẹlu eeyan ti ko pe ogun, ko to di pe Ọlọrun gbe agbara iṣẹ nla rẹ dide, ti awọn eeyan si bẹrẹ si i pọ si lojoojumọ.
Nigba to n sọrọ nipa idi ti wọn ṣe fẹẹ kọ gbọngan tuntun naa, Wolii Ayọdele sọ pe Ọlọrun ti bukun ṣọọṣi naa lati kọ gbọngan nla ti yoo gba awọn eeyan rẹpẹtẹ lati jọsin lẹẹkan ṣoṣo.
Yatọ si eyi, a gbọ pe Wolii Ayọdele ti kọ ọfiisi aragbayamuyamu olowo iyebiye to ba ti igbalode lọ, eyi ti wọn yoo ṣi laipẹ yii.
No comments:
Post a Comment