Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti tu awọn aṣiri kan tẹnikẹni ko tii gbọ ri sita, to si ni oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti fi tikẹẹti sẹnetọ bẹ o, lati darapọ mọ ẹgbẹ naa.
Wike sọ pe lara awọn ọna ti Aṣiwaju Tinubu n wa lati fi fa oju oun mọra ni ti tikẹẹti to fẹẹ f'oun lọfẹẹ oun, koun ba a le ṣiṣẹ fun un ninu idibo ọdun 2023 to n bọ lọna yii, ṣugbọn to loun ko gba a.
Oni tii ṣe ọjọ Ẹti, Furaidee ni Wike sọrọ naa jade sita, to si ni anfaani kekere to ṣi silẹ fun Tinubu lati wa a ba oun ni bi oludije sipo aarẹ kan naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar ko ṣe mu awọn ileri rẹ ṣẹ lẹyin to jawe olubori nibi idibo abẹle ẹgbẹ naa to waye niluu Abuja.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Mio gbe apoti ki n le di igbakeji aarẹ, mi o kii ṣe bi awọn yooku to jẹ pe ṣe ni wọn sare lọọ gba fọọmu aṣofin papọ mọ ti aarẹ, idi ree to fi jẹ pe nigba ti Tinubu loun yoo fun mi fọọmu sẹnetọ, mi o da a lohun.’’
No comments:
Post a Comment