Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ lori gendekunrin, ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Ismail Adewuyi ti wọn ka ori ati ifun oku mọ lọwọ niluu Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun.
Itẹku awọn Musulumi to wa lagbegbe Oke Yidi Abẹrẹ, Ẹdẹ, ipinlẹ naa la gbọ pe ọwọ ti tẹ Ismail.
Ọkan lara awọn fijilante to n ṣiṣẹ kaakiri loru la gbọ rọwọ to Ismail, lakoko to ṣẹṣẹ ge ori oku obinrin naa tan, ni nnkan bi aago kan kọja iṣẹju mẹẹdọgbọn, oru, ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii.
Yẹmisi Ọpalọla to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa f'idi rẹ mulẹ, to si ni iwadii ti n lọ lọwọ.
No comments:
Post a Comment