Niṣe lọrọ naa dabi ẹfun ati eedi, nigba ti wọn sọ pe afurasi ajinigbe kan, Onyeka Ozoh ji eyan kan gbe, to si gba owo ati mọto lọwọ ẹni naa, iyẹn ninu oṣu kẹjọ, ọdun yii.
Bo tilẹ jẹ pe iroyin ko tii fidi rẹ mulẹ wi pe ẹni ti Ozoh jigbe lo ni mọto ti wọn gba lọwọ ẹ, ṣugbọn ohun ti a gbọ ni pe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii ni ọwọ tẹ ẹ ni buba ibi to sapamọ si.
AWIKONKO gbọ pe agbegbe Issele-uku to wa nipinlẹ Anambra ni ọwọ ti tẹ Ozoh, lẹyin ti wọn tọpinpin mọto naa de ọdọ ẹ.
Bọwọ ṣe tẹ ẹ lo ṣalaye pe miliọnu kan ataabọ naira loun ra mọto naa ni ọja Onitsha, ati pe ẹni to n lo o tẹlẹ lo ni gbogbo awọn ojulowo iwe rẹ lọwọ.
DSP Bright Edafe, to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa sọ pe mọto Toyota Camry, alawọ pupa ni wọn gba lọwọ Ozoh, to si ni iwadii ti n lọ lọwọ lori ẹ.
No comments:
Post a Comment