Ọwọ tẹ ajinigbe meji pẹlu ibọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 22, 2022

Ọwọ tẹ ajinigbe meji pẹlu ibọn


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti tẹ awọn meji kan ti wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ ajinigbe lọ.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Agbarho, ijọba ibilẹ Ariwa Ughelli lọwọ ti tẹ awọn mejeeji, nibi ti wọn sapamọ si.

Bright Ẹdafe to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa lakoko to n f'idi iroyin ọhun mulẹ l'Ọjọru, Wẹsidee to kọja fi orukọ awọn meji naa sita gẹgẹ bii Felix Itoje ati Israel Adam.
 
Obinrin kan la gbọ pe awọn ajinigbe naa jigbe l'ọsẹ to kọja.
 
Ẹdafe ni ọjọ kejidinlogun, oṣu yii ni wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo nipa wi pe awọn ajinigbe kan ti ji obinrin kan gbe, ko to di pe awọn ọlọpaa ẹkun Agbarho dide lati ṣe iwadii.
 
Ninu iwadii lọwọ ti tẹ Felix Itoje, ẹni ọdun mejilelọgbọn ni ibi ti wọn ti n tun mọto ṣe, eyi to wa loju ọna Warri si Sapẹlẹ.
 
O ni bi iwadii ṣe n tẹ siwaju lọwọ tun pada tẹ ẹnikeji rẹ, Israel Adam, ọmọ ọdun mejilelogun pẹlu ibọn lagbegbe Uvwiamuge to wa ni Agbarho, ijọba ibilẹ Ughelli North.
 
O wa fi kun ọrọ ẹ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI