Oṣelu ni Dapọ Abiọdun fẹẹ fi yan ọba le awọn ara Ibu Onipẹ lori - Harrison pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 11, 2022

Oṣelu ni Dapọ Abiọdun fẹẹ fi yan ọba le awọn ara Ibu Onipẹ lori - Harrison pariwo sita


Oludije s'ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Alliance Action Congress, Ọnarebu Adeyẹmi Harrison ti bu ẹnu atẹ lu bi Gomina Dapọ Abiọdun ṣe n gbero lati yan ọba le awọn araalu Ibu Onipẹ to wa n'ijọba ibilẹ Ogun Waterside lori.
 
L'ọjọ Abamẹta, Satide ana ni Ọnarebu Harrison sọrọ yii jade, to si ni gbogbo ọna ni Gomina Abiọdun n wa lati yan ajoji le wọn lori gẹgẹ bi ọba, eyi to sọ pe ko bojumu to fun idagbasoke eto oye ati ọba jijẹ.
 
Harrison ni yatọ si pe ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni Gomina Abiọdun n pọn lẹyin lati di Ọba Ibu Onipẹ, o ni ko ba ila ofin yiyan ọba mu, ko jẹ pe gomina ni yoo fa ẹni ti yoo ba di ọba kalẹ, ati pe iwa oṣelu ti ko yẹ ni.
 
Ọkunrin naa to ti figba kan ri jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun tẹsiwaju pe latigba ti ọba ana ti waja, ni igbesẹ ti bẹrẹ lati yan ọba miran, ṣugbọn ti Gomina Abiọdun sọ oju ati eti rẹ nu si i.
 
O ni ki i ṣe asiko ti oṣelu n bọ yii ni Abiọdun yoo wa dide lati sọ pe oun fẹẹ yan ọba fun wa, o ni ko ṣee ṣe nitori pe ṣe lo fẹẹ fi tako oun lakoko oṣelu to n bọ lọna.
 
Siwaju si i lo sọ pe ọdun kẹta ree ti awọn ti ni ọba gbẹyin nibẹ, ko wa a yẹ ko jẹ iru asiko yii ni Dapọ yoo wa sọ pe ajoji ti wọn fi ipo oloye ta lọrẹ lo maa wa di ọba le wọn lori, eyi to sọ pe awọn araalu ko fẹ bẹẹ.
 
O wa rawọ ẹbẹ si Gomina Abiọdun lati ma ṣe da si ọrọ yiyan ọba niluu Ibu Onipẹ, o ni dibo ko maa da si nnkan ti ko kan an, ko tete gbajumọ ọrọ idibo to kan an, ati pe ko fi awọn idile to n jẹ ọba at'awọn afọbajẹ silẹ lati ṣe ohun to ba tọ nipa yiyan ẹni ti awọn araalu naa n fẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI