Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan ni awọn eeyan ṣi fi wa ninu iyalẹnu wi pe ọmọbinrin arẹwa kan gba ẹmi ara rẹ nitori ti ọkọ afẹsọna ba ẹlomiran lọ.
Ọlaitan Adonis ni wọn pe orukọ ọmọbinrin arẹwa ọhun, ti wọn sọ pe niṣe lo gbe nnkan jẹ to fi ku, pẹlu inu to bii.
Iyẹn nikan tun kọ, wọn sọ pe ọkọ afẹsọna rẹ naa, Ọla Saheed tun lo owo Ọlaitan to wa lọwọ ẹ lati fi ṣe igbeyawo pẹlu obinrin to ba lọ.
Ọdun keje ree ti a gbọ pe Ọlaitan ati Saheed ti n ba ara wọn bọ gẹgẹ bi ololufẹ, ti wọn si ti jọ ṣe ileri funra wọn pe wọn ko nii yara.
Gbogbo owo ti wọn sọ pe Ọlaitan n ri nidii iṣẹ to yan laayo, apo owo ile ifowopamọ ti Saheed lo n ko o si, nitori ifẹ to ni sii.
Owo naa ni wọn sọ pe Saheed fi fẹ obinrin miran lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.
Awọn kan ti aṣiri naa tu si lọwọ ni wọn ṣalaye fun Ọlaitan pe ọkọ afẹsọna rẹ fẹẹ ṣe igbeyawo pẹlu obinrin miran.
Loju ẹsẹ ni wọn lo lọ gbe oogun jẹ, to si gbabẹ sọda s'ọrun aremabọ.
A tiẹ tun gbọ pe Ọlaitan ṣi fi ẹgbẹrun mẹwaa naira ranṣẹ si Saheed lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja.
No comments:
Post a Comment