Ọpẹ o! Ìyáálé ilé tó dàwátì ní ìpínlẹ̀ Ògùn ti padà sílé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 13, 2022

Ọpẹ o! Ìyáálé ilé tó dàwátì ní ìpínlẹ̀ Ògùn ti padà sílé


Inu idunnu ati ayọ nla l'awọn mọlẹbi iyaale ile kan, Arabinrin Sandra Ọmọbọlanle Ataruno wa, ti wọn lo dawati lopin ọsẹ to kọja yii, lagbegbe Ijoko si Ojo Oore nipinlẹ Ogun lori bi wọn ṣe rii pada.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn amookunṣeka ni wọn ji Arabinrin Sandra gbe, loju ọna ibi to dagbere ko to kuro nile.

Irọlẹ ana, ọjọ Aje, Mọnde la gbọ pe wọn pada ri Sandra, lẹyin ti awọn ajinigbe jiigbe, bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ boya wọn san owo ki wọn to gba a silẹ.
 
Wọn ni ko to kuro nile, o dagbere pe agbegbe Oju Oore loun n lọ, iyẹn ni nnkan bi aago mẹta ọsan, ṣugbọn ti wọn sọ pe ko pada sile latigba naa titi di asiko yii.
 
Gbogbo akitiyan awọn mọlẹbi obinrin naa lati mọ ibi to wa titi di asiko yii la gbọ pe o ja si pabo, ti wọn si ti lọ fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti lati ran wọn lọwọ.

Ni bayii, orin ọpẹ l'awọn mọlẹbi obinrin naa n kọ lori bi wọn ṣe rii pada.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI