Ijọba ipinlẹ Kwara ti rọ awọn agbaṣẹṣe to n ṣiṣẹ lori omi ẹrọ igbalode to n lọwọ niluu Jẹbba, ijọba ibilẹ Moro lati tete pari iṣẹ naa, ki asiko too lọ.
Ohun ti a gbọ ni pe iṣẹ naa ti de ipele kejileaadọrin lati fi pari, iyẹn lakoko ti Kọmiṣanna f'ọrọ eto akanṣe iṣẹ, Fẹmi Agbaje ṣabẹwo sibẹ.
Ijọba ipinlẹ naa sọ pe niwọn igba ti ijọba n ṣe ojuṣe wọn, o ti di dandan fun awọn agbaṣẹṣe ti wọn gbe iṣẹ le lọwọ lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ, lai yẹ adehun.
Nigba to n sọrọ nibi ti iṣẹ naa ti n lọ lọwọ l'Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, Ọnarebu Wahab Fẹmi Agbaje kọminu lori bi iṣẹ naa ṣe n wọlẹ, ti ko si ya bo ṣe yẹ.
O ni o ti dandan fun awọn agbaṣẹṣe lati sun ṣokoto wọn soke, ki wọn si tẹle adehun ti wọn tọwọ bọ pẹlu ijọba Kwara, ki ohun gbogbo le lọ bo ti tọ ati bo ti yẹ.
No comments:
Post a Comment