Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kin-in-ni, Oluwo tilu Iwo ti sọ pe 'ori ẹlẹgan lo bajẹ', f'awọn to sọ pe awọn alalẹ ilu Iwo maa binu s'oun nitori ti ko gba oriṣa sinsin laaye niluu Iwo, ipinlẹ Ọṣun.
Laipẹ yii ni Oluwoo sọrọ naa ninu ọrọ to kọ sori ikanni ayelujara ti fesibuuku rẹ.
O ni "Nitori to kọ lati f'ori balẹ f'awọn alalẹ, wọn ni ko le yee, wọn l'awọn oriṣa maa binu sii. Ọdun kin-in-ni, ọdun keji, ọdun kẹta, ọdun kẹrin, ọdun karun-un, ọdun kẹfa, ọdun keje ati ọdun kẹjọ to n lọ lọwọ yii.
"Nigba wo ni ibinu wọn yoo dide? Nigba ti o ba n da jagun, rii daju pe o wa lori are rẹ. Bi o ba wa lori are pẹlu Ọlọrun, alagbara ni ẹ. Igba diẹ naa ni.
No comments:
Post a Comment