Iroyin tuntun to jade sita ni Naijiria lakoko yii, iroyin ayọ nla lo jẹ pẹlu awọn amofin ti ko din ni mejilelọgọta ṣe gba oye alẹnulọrọ agba ti a mọ si Senior Advocate of Nigeria, SAN.
Ninu wọn la ti ri Ọjọgbọn nipa ofin mẹsan, awọn agbẹjọro mẹta ọtọọtọ ti wọn n ṣiṣẹ fun ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC.
Ajọ onimọ nipa ofin nni, Legal Practitioners’ Privileges Committee (LPPC) labẹ alaga iṣakoso wọn, Adajọ agba ni Naijiria, Olukayọde Ariwoọla la gbọ pe o fi oye naa da gbogbo wọn lọla.
Hajo Sarki Bello to jẹ olugbaniwọle agba (Chief Registrar) nile ẹjọ agba orileede yii, lo gbe iroyin naa jade nirọle oni, Tọsidee.
Lara awọn Ọjọgbọn naa ni: Kathleen Ebelechukwu Okafor, Muhammed Taofeeq Abdulrasaq, Amokaye Oludayọ Gabriel, Ismail Adeniyi Ọlatunbọsun, Abdullahi Sheu Zuru, Joy Ngozi Ezeilo, Theodore Bala Maiyaki,
Awọn yooku ni Ọlaide Abass Gbadamọsi ati Chimezie Kingsley Okorie.
No comments:
Post a Comment