Ọwọ ileeṣẹ eto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka ti ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn marundinlaadọta kan ti wọn fura si pe ọdaran ni wọn, ti wọn si ti n ṣe iwadii wọnn lọwọ.
Aarin ọsẹ meji la gbọ pe ọwọ tẹ gbogbo wọn ni agbegbe ọtọọtọ laaarin ipinlẹ naa
Nigba to n f'oju wọn han lagbegbe Alagbaka niluu Akurẹ, olori awọn Amọtẹkun n'ipinlẹ naa, Adetunji Adelẹyẹ sọ pe mẹjọ ninu awọn ọdaran naa jẹ ajinigbe.
Adetunji sọ pe awọn to gbọ nipa awọn ọdaran naa tipẹtipẹ, eyi to jẹ ki awọn bẹrẹ iṣẹ iwadii to mu ki ọwọ tẹ gbogbo wọn.
O wa sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ, ko to di pe wọn f'oju wọn ba ile ẹjọ.
No comments:
Post a Comment