Nitori ẹtaanu ti wọn ni si Tinubu ni ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣe tẹle Peter Obi, gbogbo wọn maa lulẹ ni - Keyamo ju bọmbu ọrọ sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 27, 2022

Nitori ẹtaanu ti wọn ni si Tinubu ni ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣe tẹle Peter Obi, gbogbo wọn maa lulẹ ni - Keyamo ju bọmbu ọrọ sita


Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lorileede Naijiria, Festus Keyamo ti sọ pe nitori iwa ẹtaanu ti ẹgbẹ Afẹnifẹre ni si Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ni ẹgbẹ naa ṣe lawọn yoo ṣatilẹyin fun oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi.

Keyamo sọrọ yii lẹyin ti olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ayọ Adebanjọ fa ọwọ Peter Obi soke gẹgẹ bi oludije ti wọn yoo ṣatilẹyin fun lọdun 2023.

Ori ikanni ayelujara ti Twitter ni Keyamo ti ju bọmbu ọrọ naa lonio, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nibi to ti sọ pe ko si oludije ti ẹgbẹ naa ṣatilẹyin fun, ti kii pada lulẹ.

Siwaju sii lo sọ pe gbogbo awọn oludije ti ẹgbẹ naa tẹle lakoko eto idibo meji to waye lerawọn sẹyin ni wọn fidi rẹmi, ti ko si seyi to jawe olubori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI