Nibi ti Ibrahim ti fẹẹ fi ayederu ibọn ja ọkada gba lọwọ ẹṣọ aabo So-Safe Corps ti tẹ ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 11, 2022

Nibi ti Ibrahim ti fẹẹ fi ayederu ibọn ja ọkada gba lọwọ ẹṣọ aabo So-Safe Corps ti tẹ ẹ


Ọrọ buruku toun tẹrin l'ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii nigba ti wọn sọ pe gendekunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Ibrahim Oluwaṣeun fẹẹ fi ayederu ibọn ja ọkada gba lọwọ ọlọkada lagbegbe Idiroko, ipinlẹ Ogun.

A gbọ pe Ibrahim to n gbe ni agboole Olorogbo to wa ni agbegbe Asheko/Ibatẹfin, ijọba ibilẹ Ipokia lo pe Bamidele Mujeeb, toun jẹ ọlọkada to fẹẹ ja gba ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa lati gbe oun.

Wọn ni adugbo Afẹriku to wa ni Idiroko ni Ibrahim ti sọ pe ki ọlọkada naa gbe oun lọ si adugbo Ọbalana to wa loju ọna Bebe, eyi to jade si orileede olominira Bẹnin.
 
Agbẹnusọ So-Safe Corps, Mọruf Yusuf to gbe iroyin ọhun si wa leti sọ pe bi wọn ṣe de agbegbe kan, ni Ibrahim sọ fun ọlọkada yii lati gba ọna tooro kan, ki wọn le tete de ibi ti wọn n lọ, lai mọ pe o niṣẹ buruku kan l'ọkan to fẹẹ ṣe f'oun.
 
Bi wọn ṣe ya si ọna tooro naa, la gbọ pe Ibrahim fa ayederu ibọn yọ si ọlọkada yii, to si ni ko mu ọkan laaarin ẹmi ẹ ati ọkada rẹ. Loju ẹsẹ la gbọ pe ọlọkada naa ti sare bọ silẹ lai mọ pe ayederu ibọn ni, to si n rababa bẹbẹ fun ẹmi ẹ.
 
Gbogbo asiko yii, awọn mejeeji ko mọ pe awọn ẹṣọ aabo So-Safe t'awọn n ṣiṣẹ aabo kaakiri n wo iṣesi wọn, ti wọn si n fi wọn rẹrin. Nibi ti Ibrahim ti fẹ maa gbe ọkada ọhun salọ ni wọn ti yọ si i lojiji, ti wọn si mu.
 
Mọruf jẹ ko ye wa pe loju ẹsẹ nibẹ ni Ibrahim ti n ka boroboro pe ki wọn foju aanu wo oun, ati pe kii ṣe akọkọ ree toun yoo ji ọkada gbe, ati pe iṣẹ eṣu ni.

O wa sọ pe ọga awọn, Olusọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa Ibrahim le awọn ọlọpaa ẹkun Idiroko lọwọ lati tubọ ṣe iwadii rẹ.

Siwaju si i lati f'idi iroyin naa mulẹ, ṣugbọn gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ lo ja si pabo titi digba ti a pari akojọpọ iroyin yii.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI