Afaimọ ni ko ma jẹ pe ọgba ẹwọn ni gendekunrin, ẹni ọdun marundinlogoji kan, Yẹkini Ọpẹyẹmi ti wọn lo ṣẹṣẹ de lati ẹwọn ọdun mẹrin ti wọn juu si yoo ti lo eyi to ku nigbesi aye rẹ, lori bi ọwọ tun ṣe pada tẹ ẹ lori ẹsun idigunjale.
Jẹnẹretọ nla meji ọtọọtọ la gbọ pe Yẹkini ati awọn kan t'awọn ti na papa bora jigbe lagbegbe Garaaji tuntun ti Ọjọta, iyẹn Ọjọta New Garage.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ọlọpaa pajawiri, iyẹn Rapid Response Squad (RRS) lo rọwọ to Yẹkini nibi toun ati awọn ti wọn jọ lọ ji awọn jẹnẹretọ ọhun gbe sinu mọto.
A gbọ pe lẹyin ti Yẹkini de lati ọgba ẹwọn, Garaaji tuntun ti Ọjọta lo ri iṣẹ si gẹgẹ bi ọlọdẹ, nibẹ si ni wọn lo ti ji jẹnẹretọ mejeeji ti wọn pe agbara wọn ni 2.8 KVA gbẹ.
Nnkan bi aago mẹrin aarọ kutu la gbọ pe ọwọ tẹ ẹ nitosi Odo-Iya Alaro, Ọjọta lọwọ tẹ ẹ. Awọn jẹnẹretọ ọhun ni wọn pe ni Firman ati Tigmax ti agbara ọkọọkan wọn jẹ 2.8 KVA.
Wọn ni ibi ti wọn ti n gbe e sinu mọto Volkswagen Golf l'awọn ẹṣọ aabo RRS ti ri wọn, bi wọn si ṣe rii pe aṣiri ti tu, lo mu k'awọn to wa ninu mọto ọhun juba ehoro, ti wọn si fi Yẹkini silẹ.
Ẹẹmẹrin ọtọọtọ la gbọ pe Yẹkini ti lọ sẹwọn lori ẹsun ọtọọtọ ti wọn fi kan an, ti wọn si ni ko tun le ṣalaye daadaa nipa ibi ti wọn ti ri jẹnẹretọ ti wọn fẹẹ jigbe salọ.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Abiọdun Alabi, nigba to n gbe oṣuba kare fun alakoso agba fun ikọ RRS naa, CSP Yinka Ẹgbẹyẹmi, paṣẹ pe ki wọn tare Yẹkini si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si ẹsun ọdaran, eyi to wa ni Panti lati tẹsiwaju iwadii, ko to di pe wọno f'oju ẹ ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment