Gbogbo eto la gbọ pe o ti fẹẹ pari bayii, fun bi gbajugbaja sọrọsọrọ agbaye nni, Ọgbẹni Kọlawọle Atanda Adejojo ti ọpọ awọn eeyan mọ si Kasnaty Sugar ṣe fẹẹ fi ọpọlọpọ ounjẹ ati ẹbun tọrẹ f'awọn to ku diẹ kaato fun kaakiri orileede Naijiria, bẹrẹ lati ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun to fi ṣe ibugbe.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ ti a wa yii, iyẹn ọjọ kẹsan, oṣu kẹsan yii gan-an ni eto ọhun fẹẹ waye, nibi ti awọn onibaara yoo ti bọ saye pẹlu ẹbun ounjẹ naa.
Bo tilẹ jẹ a ko tii le sọ pato ibi ti eto naa yoo ti waye, ṣugbọn a gbọ pe kaakiri ori ayelujara, paapaa ikanni bii Fesibuuku, Insitagiraamu ati YouTube l'awọn eeyan kaakiri agbaye yoo ti ma a wo o.
Awọn ololufẹ Kasnaty Sugar kaakiri agbaye la gbọ pe wọn fẹẹ ṣagbatẹru eto naa, ti wọn si ti fi owo at'awọn eroja ti yoo mu ki ọjọ naa larinrin ranṣẹ.
Bakan naa ni Kasnaty tun fẹẹ lo anfaani eto naa ṣayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun iyawo ẹ, Alaaja Sẹmiat Oyindamọla Adejojo.
Nitori ifẹ ti ọkunrin, ọmọ bibi ipinlẹ Ọṣun naa to da yatọ laaarin awọn ṣorọsọrọ ẹgbẹ rẹ ni si iyawo rẹ, ni wọn lo fa a to fi fẹẹ ṣe ayẹyẹ nla fun un.
Ọjọ naa la gbọ pe iyawo Kasnaty Sugar fẹẹ pe ogoji ọdun loke eepe, eyi to jẹ ki ọkunrin naa fẹẹ dana ariya rẹpẹtẹ, paapaa lati fi ṣe iranlọwọ f'awọn onibaara.
Ibeere iyalẹnu t'awọn kan n beere bayii ni pe nibo ni Kasnaty Sugar ti ri iyawo tuntun, ati pe ṣe loootọ ni iyawo Kasnaty, ti wọn ṣe igbeyawo lọdun 2012 ko ti i jade laye ni, paapaa bo ṣe jẹ ojoojumọ lo maa n jẹ ọrọ rẹ lẹnu lori redio ati ayelujara kaakiri.
Laipẹ yii la gbọ pe Kasnaty Sugar gbe fọto oun pẹlu iyawo ẹ, Oyindamọla Sẹmiat Adejojo sori fesibuuku lati fii ku ipalẹmọ ayẹyẹ ọjọ ibi to n bọ lọna l'ọsẹ yii, eyi lo fa a ti awọn eeyan fi n beere pe ṣe obinrin naa ko ti i ku ni.
Ninu oṣu kẹsan, ọdun 2018 ni iroyin jade sita wi pe Sẹmiat Adejojo ti awọn eeyan tun n pe ni Ifọkanbalẹ, alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Semies Beauty Place jade laye, ti wọn si sinku rẹ si itẹku to wa ni agbegbe Olomore niluu Abẹokuta.
Iku obinrin naa ya pupọ awọn eeyan lẹnu, paapaa awọn ololufẹ Kasnaty.
Ọkan lara awọn to sunmọ Kasnaty, ti wọn gbe olobo naa si AWIKONKO leti jẹ ko ye wa pe ọjọ kẹsan, oṣu kẹsan, ọdun 2022 ti a wa yii ni ayẹyẹ igbeyawo Kasnaty ati Sẹmiat maa pe ọdun mẹwaa gbako, ọjọ naa tun jẹ ọjọ ti Sẹmiat maa pe ogoji ọdun loke eepẹ, ko to di pe o fi ilẹ ṣe aṣọbora.
Ẹni naa to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri tun jẹ ko ye wa pe ọjọ naa gan-an lo maa pe ọdun mẹrin gbako ti oloogbe naa jade laye.
Ni bayii, ohun ti awọn eeyan n sọ bayii ni pe o dabi ẹni pe aditu kan rọ mọ oṣu kẹsan fun Kasnaty, nitori ti a gbọ pe ọjọ naa lo tun fẹẹ fi itan nla tuntun balẹ kaakiri agbaye, ti imurasilẹ naa si ti fẹẹ pari, bo tilẹ je pe a ko tii le sọ pato ohun ti itan tuntun naa yoo jẹ.
Awọn kan ni boya nitori Sẹmiat maa pariwo nigba to wa laye pe aye ati ọrun yoo gbọ nipa ayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun oun ti asiko naa ba to, lo fa a ti Kasnaty ṣe fẹẹ fi ọpọlọpọ ẹbun tọrẹ f'awọn onibaara mọkandinlọgọrun (99 beggars).
No comments:
Post a Comment