Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ògùn yọ Ọ́nárébù méjì danù - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 13, 2022

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ògùn yọ Ọ́nárébù méjì danù


Lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun fi ofin de awọn aṣofin meji lori ẹsun magomago ti wọn fi kan wọn.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn aṣofin naa lo nii ṣe pẹlu bi àjọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC fi gbe abẹnugọn ile igbimọ aṣofin naa laipẹ yii.

Ọnarebu Dare Kadiri to n ṣoju agbegbe Ijẹbu North II, ẹni to ti figba kan ri jẹ igbakeji olori ile igbimọ naa, ko to di pe wọn yọ ọ danu ati Ọnarebu Sọlomọn Ọṣhọ, toun n ṣoju agbegbe Rẹmọ North la gbọ pe wọn fi ofin de.

Bi wọn ṣe yọ awọn mejeeji ni wọn lo lọ ni ibamu pẹlu ofin ile igbimọ aṣofin, abala kẹrinla ati ikarundinlogun, t'ọdun 2017.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI