Ijọba ipinlẹ Ọyọ labẹ Gomina Ṣeyi Makinde ti sọ ọ sita wi pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ lori ọrọ idigungbalẹ n'ipinlẹ yoo fi ẹwọn ọdun mẹwaa gbako gbara pẹlu iṣẹ aṣekara lai ni idariji.
Ninu ọrọ kọmiṣanna fọrọ eto ilẹ, ilegbee ati dagbasoke igberiko n'ipinlẹ Ọyọ, Oluṣẹgun Ọlayiwọla laipẹ yii, o ni ijọba ko le laju silẹ mọ, lati maa wo awọn ọdaran, ki wọn maa jaye famile-kintutọ.
Ori redio kan ni Oluṣẹgun ti f'idi ọrọ naa mulẹ niluu Ibadan, to si l'awọn ti gbe igbimọ af'ofinmulẹ dide lati maa lọ kaakiri, lati mọ ibi ti awọn oniṣẹburuku naa ti n ṣọṣẹ.
Bẹẹ lo kọminu lori bo ṣe sọ pe awọn ajagungbalẹ naa l'awọn alẹnulọrọ laaarin ilu to n ti wọn lẹyin, eyi to sọ pe ko dara fun ipinlẹ tabi orileede to ba n dagbasoke.
Nibẹ lo ti rawọ ẹbẹ s'awọn araalu lati wa fi ẹjọ awọn to ba n da wọn laamu sun ni ileeṣẹ wọn, tabi ileeṣẹ ọlọpaa yoowu to ba wa lagbegbe wọn.
"Awọon ajagungbalẹ yoo bẹrẹ sii lo ọdun mẹwaa l'ẹwọn bayii lai ni anfaani lati san owo itanran. Koda, awọn to ba ni nnkan ṣe pẹlu ẹsun ijagungbalẹ yoo san idaji miliọnu naira tabi ẹgbẹrun lọna igba, iyẹn bi ẹṣẹ wọn ba ṣe pọ to."
No comments:
Post a Comment