Eto Aabo: Ijọba Kwara tun ba ileeṣẹ ologun ṣadehun tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 29, 2022

Eto Aabo: Ijọba Kwara tun ba ileeṣẹ ologun ṣadehun tuntun


Lojuna lati le jẹ ki awọn ara ati olugbe ipinlẹ Kwara maa gbe ninu alaafia, lai si ibẹrubojo, ijọba ipinlẹ naa ti ba ileeṣẹ ologun orileede yii, ẹka ti ipinlẹ Kwara ṣe adehun to lọọrin.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii la gbọ pe igbakeji gomina, Kayọde Alabi ba ileeṣẹ ologun ṣe ipade papọ, pẹlu erongba lati tubọ maa daabo bo ẹmi ati dukia araalu.

Nigba to n gba ẹnu Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọrọ, Alabi jẹ ko di mimọ pe ijọba yoo tubọ maa ṣe atilẹyin to ba yẹ fun ileeṣẹ ologun, paapaa awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku, ki alaafia tubọ le jinlẹ si daadaa nipinlẹ naa.
 
O sọrọ yii lakoko to n gba ọga agba ileeṣẹ ologun, ti Commanding 2 Division lati ilu Ibadan, Ọgagun Aminu Shehu Chinade lalejo, nibi abẹwo to ṣe wa siluu Ilọrin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI