Boroboro l'awọn afurasi adigunjale mẹrin kan n ka, nigba tọwọ palaba wọn segi laipe yii lagbegbe Ọlọkọpupọ, Atan Ọta, ijọna ibilẹ Ado-Odo Ọta, ipinlẹ Ogun.
Ibi ti wọn l'awọn adigunjale naa ti n gbiyanju lati fo fẹnsi wọnu ọgba ọkan lara awọn ile ti wọn ti fẹẹ jale lọwọ ti tẹ wọn ni nnkan bi aago marun kọja iṣẹju mẹrindonlọgbọn, ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ eto aabo ipinlẹ Ogun, iyẹn So-Safe Corps, Mọruf Yusuf to gbe iroyin naa si wa leti jẹ ko di mimọ pe ẹka ileese wọn, ti ẹkun Atan, eyi ti alakaso gbogbo ẹkun Agbara, ACC Adebesin Lukman jẹ olori wọn l'awọn adigunjale naa ha si lọwọ.
Mọruf sọ pe ile mẹta ọtọọtọ l'awọn adigunjale naa wọ lagbegbe ti wọn ti lọ ṣọṣẹ, ko to di pe ọwọ tẹ wọn.
Ibi ti wọn ti n ge waya ina ti wọn fi daabo bo fẹnsi ile kan ti wọn fẹẹ wọ ni aṣiri wọn ti tu, gẹgẹ bi Mọruf ṣe ṣalaye, to si tun jẹ ko ye wa pe meje ni gbogbo awọn adigunjale naa, ṣugbọn to ni awọn yooku na papa bora.
Nigba to n fi orukọ awọn tọwọ tẹ naa sita, o ni Ikechukwu Oligbo, ẹni ọdun marundinlogoji; Fidelix Nwakwo, ẹni ọdun mejilelọgbọn; ati Chinedu Eze, ẹni ọdun mẹtadinlogoji l'awọn ti ọwọ tẹ.
Bakan naa lo tun fi kun un pe ọwọ tun pada tẹ Nuru Ahmẹd, ọmọ ọdun mẹrinlelogun kan to n gbe lagbegbe Alala Rago, ipinlẹ Eko, ẹni ti wọn lo maa n ra ẹru, paapaa foonu t'awọn ole ba ti jigbe.
Iwadii pada fidi rẹ mulẹ pe ọwọ ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ugor ni ibọn ilewọ ti wọn maa n lo fi ṣiṣẹ wa, ṣugbọn ti wọn loun naa ti juba ehoro.
Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn ni iPhone meje ọtọọtọ, Toyota Rav 4 ti nọmba rẹ jẹ KSF 92 GT, foonu Techno meji, bẹliiti meji, fila dudu kan, ati owo to din diẹ ni ẹgbẹrun marun naira (N4, 840:00).
Mọruf fi ye wa pe ọga awọn Olusọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa gtbogbo awọn tọwọ tẹ naa le ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Atan lọwọ, lati tubọ tẹsiwaju iwadii, ko to di pe wọn f'oju wọn ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment