Biliọnu mejila din diẹ lo poora ni Kwara laaarin ọdun 2011 si 2019 - Iwadii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 1, 2022

Biliọnu mejila din diẹ lo poora ni Kwara laaarin ọdun 2011 si 2019 - Iwadii


Iwadii awọn onimọ nipa eto iṣuna owo ti f'idi rẹ mulẹ wi pe owo to din ni diẹ ni biliọnu mejila, iyẹn N11.9b naira lo poora lapo ijọba ipinlẹ Kwara laaarin ọdun 2011 si ọdun 2019.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ki i ṣe pe wọn fi awọn owo naa ṣiṣẹ akanṣe s'ipinlẹ naa f'awọn araalu, bi ko ṣe pe ko s'ẹni to le sọ pato ohun ti wọn fi owo naa ṣe.
 
Ninu iwadii ọhun la ti gbọ pe biliọnu meji naira ni wọn gba jade ni banki, ti ki i ṣe pe akọsilẹ wa fun un pe wọn fi ṣiṣẹ akanṣe kan tabi wi pe o jẹ lilo fun eto akanṣe ijọba. Aarin ọjọ mẹjọ pere la gbọ pe wọn fi gba owo naa jade ni banki ninu oṣu keji, ọdun 2019, iyẹn nigba to ku bi oṣu kan ki eto idibo waye.
 
Anthony Iniomoh n'igba to n sọrọ nibi to ti n gbe abajade iwadii naa siwaju Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lonii, Ọjọbọ, Tọside, sọ pe ipele meji ni esi abajade naa wa.
 
O ṣapejuwe abajade ọna meji ọhun gẹgẹ bi i Internally Generated Revenue; Capital Receipts; Internal and External Loans; Recurrent / Overhead Expenditure; Personnel Cost (Salaries and Wages); Capital Expenditure; Assets Disposed; Kwara State Internal Revenue Service; Infrastructural Fund Kwara (IFK); Harmony Holdings Limited; at'awọn miran.
 
Ẹ ka ẹkunrẹrẹ iroyin naa nibi: ẸKUNRẸRẸ IROYIN

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI