Lẹyin ipade ti ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorileede Naijiri, iyẹn National Association of Nigerian Students (NANS) ṣe papọ pẹlu ọga ọlọpaa ipinlẹ Kwara, wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn ko nii darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn yooku ninu iwọde ifẹhonuhan ti wọn n ṣe lati ti awọn papakọ ofurufu pa, latari iyanṣẹlodi awọn olukọ, iyẹn ASUU to n lọ lọwọ.
Bẹ o ba gbagbe, l'ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ NANS kede sita wi pe awọn yoo ti gbogbo papakọ ofurufu orileede Naijiria pa nitori b'awọn akẹkọọ ṣe wa nile, lai lọ sileewe lati bi oṣu meje sẹyin.
A gbọ pe bi awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa lapapọ ṣe gbe ọrọ yii sita ni kọmiṣanna ọlọpaa Kwara ti ranṣẹ pe awọn oloye ẹgbẹ naa n'ipinlẹ ọhun, lati ba wọn jiroro.
Lẹyin ijororo naa ni wọn fi ẹnu ko pe awọn ko ni i darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn yooku kaakiri Naijiria, ati pe awọn yoo gba alaafia laaye n'ipinlẹ wọn.
Ninu ọrọ rẹ, ọga ọlọpaa naa, CP Paul Odama sọ pe ọna ọtọọtọ ni k'awọn akẹkọọ gba yanju iṣoro wọn, ati pe awọn ko fẹ ki awọn tọọgi tun wa da iwọde naa ru, gẹgẹ bi eyi to waye lasiko EDNSARS, tọdun 2020.
No comments:
Post a Comment