Àṣírí tú o! Wọ́n l'ẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pẹ̀lú ENetSuD láti tẹ ayédèrú ìwé ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 21, 2022

Àṣírí tú o! Wọ́n l'ẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pẹ̀lú ENetSuD láti tẹ ayédèrú ìwé ní Kwara


Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe afi ki ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo kumọkumọ lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC tete gbe igbesẹ lati ṣe iwadii ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Kwara.

Ohun ti a gbọ ni pe iwe adehun ti ẹgbẹ oṣelu PDP tọwọ bọ pẹlu ileeṣẹ ENetSuD, iyẹn Elites Network for Sustainable Development ni lati ba dabaru iṣakoso Gomina AbddulRahman AbdulRazaq nipinlẹ naa.

Wọn ni gbogbo erongba wọn ni lati ba iṣakoso naa lorukọ jẹ, lati le fi ẹsun ti kii ṣe tijọba kan an nipa awọn ayederu iwe ti wọn lọ ṣe ayidayida rẹ.

Ọsẹ to kọja yii la gbọ pe awọn mejeeji tọwọ bọwe adehun naa, eyi ti aṣiri rẹ ti wa lu sita bayii.

ENetSuD ti ọpọ awọn eeyan ti bu ẹnu atẹ lu wi pe ẹni ti o ba gbe owo to pọ kalẹ ni wọn maa n gbe iṣẹ fun. Bẹ o ba si gbagbe, awọn ni wọn tọwọ bọ iwe adehun pẹlu ajọ alaanu kan ti wọn pe ni Gobir Organisation Foundation, eyi to jẹ ti oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Young Progressive Party, YPP.

Lara àwọn to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe gbogbo ọna ni PDP n wa lati dori iṣakoso APC kodo nipinlẹ Kwara, eyi ti wọn l'awọn kan n tu aṣiri wọn sita ko to pẹ ju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI