Epe rabande-rabande l'awọn ara ilu Oṣogbo n'ipinlẹ Ọṣun n ṣẹ fun baba agbalagba, ẹni ọdun mejidinlaadọrin, 68 kan, lori bo ṣe fipa ja ibale ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹwaa.
Ayọdele Faremi ni wọn pe orukọ baba agba radarada naa ti wọn sọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ bayii, to si ti wa nibi to ti n ka boroboro n'ipa bo ṣe f'ipa ba ọmọdebinrin naa laṣepọ.
Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii la gbọ pe ọwọ tẹ Ayọdele, lẹyin ti wọn lọ fi ọrọ rẹ to awọn ọlọpaa Dada Estate to wa niluu Oṣogbo leti.
Fọlaṣade Aṣafa la gbọ pe o lọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti wi pe Ayọdele f'ipa ba ọmọ aburo oun laṣepọ, nipa jija ibale rẹ pẹlu ipa, to si ni ko gbọdọ sọ fẹnikẹni.
AWIKONKO gbọ pe ẹẹmeji ọtọọtọ ni baba agbaaya naa ti f'ipa ba ọmọ oun laṣepọ ninu oṣu karun-un, ọdun yii, to si n dunkooko mọ ọn pe oun yoo luu pa to ba ṣeeṣi jẹwọ.
Wọn ni ṣe lo maa n fun ọmọ naa ni oogun kan lati mu, nigbakugba to ba ti fipa ba a laṣepọ tan, ti a si gbọ pe o ti f'ipa ba ọmọ laṣepọ lẹẹkan ṣoṣo ninu oṣu kẹjọ to kọja.
Ẹsun mẹta ọtọọtọ la gbọ pe wọn fi kan Ayọdele niwaju ile ẹjọ majisireeti to wa niluu Oṣogbo, l'ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii.
Onidajọ O.A Daramọla to gbọ ẹjọ naa ti wa paṣẹ pe ki Ayọdele ṣi wa latimọle titi di ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii ti igbẹjọ miran yoo tun pada waye.
No comments:
Post a Comment