APC sun akoko ipolongo idibo siwaju - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 27, 2022

APC sun akoko ipolongo idibo siwaju


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lorileede Naijiria ti kede sita wi pe ohun ti sun akoko ipolongo idibo ọdun 2023 siwaju, ti ko si kede ọjọ ti yoo jẹ.

L'ọsẹ to kọja yii ni ajo eleto idibo apapọ ni Naijiria fi orukọ gbogbo awọn adije sipo aarẹ, ile igbimọ aṣofin agba, ati ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja sita, ti wọn si tun kede wi pe eto ipolongo idibo yoo bẹrẹ lẹkunrẹrẹ l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Oni tii ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni alakoso agba pata fun ipolongo idibo ipo Aarẹ ti Tinubu/Shettima, Simon Lalong kede sita

Ninu atẹjade ti Lalong fi sita, lo ti jẹ ko di mimọ pe igbesẹ naa waye pelu erongba lati tubọ gba awọn alẹnulọrọ nipo oṣelu sinu igbimọ iṣakoso eto idibo Tinubu/Shettima.

Lalong sọ pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ maa reti ọjọ ti ipolongo idibo yoo bẹrẹ, nitori lẹyin ti eto ba ti pari, awọn yoo kede.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI