Iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ni pe alakoso eto ipolongo idibo fun oludije sipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, nipinlẹ Kwara, iyẹn Ṣọla Kafinta ti sọ pe Gomina AbddulRahman AbdulRazaq loun yoo ṣatilẹyin fun lati pada sipo gomina lẹẹkeji.
Kafinta, ẹni to lewaju ikọ to ṣe iwọde eleeyan miliọnu kan fun Obi nipinlẹ Kwara laipẹ lo sọrọ naa, to si ni oun nigbagbọ ninu iṣakoso Gomina AbdulRazaq
Ọkunrin naa to tun jẹ adẹrinpoṣonu naa tun tun jẹ ko di mimọ pe kii ṣe pe oun yoo ṣatilẹyin nikan, bi ko ṣe pe abẹ ẹgbẹ kan to pe ni Return To Power (RTP) loun yoo ti ṣiṣẹ fun gomina wọn.
AWIKONKO gbọ pe Kafinta ti lọ ṣe patako ipolongo kan lati fi kede idibo saa keji fun Gomina AbdulRazaq, to si kọ ọ sibẹ pe awọn ṣi n fẹẹ titi di ọdun 2027.
No comments:
Post a Comment